Kẹtikẹti ni awọn olugbe ipinlẹ Ọṣun tu sita lọjọru lati ṣe iwọde tako idajọ igbimọ to sọ pe Sẹnetọ Ademọla Adeleke ti ẹgbẹ osẹlu Peoples Democratic Party lo jawe olubori ninu idibo sipo gomina ipinlẹ naa to waye lọdun 2018.
Nibi iwọde naa to waye nilu Oṣogbo ni awọn to wọde ti gbe oriṣiriṣi akọle dani lati fi sọ erongba wọn.
Ọjọ Ẹti, ọjọ kejilelogun oṣu Kẹta 2019 ni meji ninu ọmọ igbimọ to gbọ ẹsun to jẹyọ latara idibo naa dajọ pe oludije PDP lo wọle.
Ṣugbọn, o da bi ẹni pe idajọ naa ko ba awọn kan lara mu ni ipinlẹ Ọṣun.
Iwọde naa ti ẹgbẹ Osun Concerned Citizens ṣe agbatẹru rẹ waye ni ilu Oṣogbo.