Afárá já sódò lẹyìn tí ọkọ̀ ojú omi kọlùú ní Brazil

Ọkọ oju omi agbero ‘fẹri’ kan ti kọlu afara kan nipinlẹ Pará lagbegbe ariwa orileede Brazil.

Ikọlu yi mu ki apa kan afara naa dawo sinu odo ti o gba ori rẹ kọja eleyi ti wọn pe orukọ rẹ ni odo Moju.

Awọn ti ọrọ na ṣoju wọn ni ọkọ meji kan ja si odo lẹyin igba ti ọkọ oju omi naa kọlu opo to di afara naa mu.

Ako ti le sọ pato iye eeyan to farapa ninu iṣẹlẹ naa ṣugbọn awọn awẹdo ti n gbiyanju lati doola ẹmi.A gbo pe eeyan marun lara awọn ti o n tukọ ọkọ oju omi naa wa lalafia.

Gomina ipinlẹ Pará,Helder Barbalho, sọ fun awọn oniroyin pe ohun to je awọn logun ni ”ṣiṣe awari awn to farakasa iṣẹlẹ naa ati ṣiṣe iranwọ fun mọlẹbi wọn”

Ọgbẹni Barbalho fi fọnran fidio iṣẹlẹ naa si oju opo Twitter rẹ.

Awọn alaṣẹ n gbiyanju lati ko awoku afara naa kuro ninu omi.

Image copyrightHANDOUT/REUTERS
Àkọlé àwòránAfara naa ṣe patakifun karakata lagbegbe naa

Awọn oniroyin lagbegbe naa n jabọ pe ayẹwọ afara naa ti wn ṣe nibẹrẹ ọdun yi ṣafihan pe opo afara naa ti n jẹ.

Wọn ni ijọba beere fun owo lati tun ṣe ṣugbọn wn ko ka ọrọ naa kundebi pe ki wọn ti afara naa pa.

Lọdun 2014, ọkọ oju omi miran kọlu opo to di afara naa mu eleyi to mu ki apa kan afara naa dawo sinu omi.

Exit mobile version