Election Update 2019: Ìpànìyàn, ìkọlù, omi gọ́tà àti awọn nkan mìíran tí a rí níbi ajọyọ̀ ìṣẹ́gun Buhari kákàkiri

Ní kete ti ajọ eleto idibo INEC gbe iwe ẹri moyege le Aarẹ Muhammadu Buhari ati igbakeji rẹ Ọjọgbọn Yemi Osinbajo lọwọ ni Abuja ni awọn ololufẹẹ wọn kakakiri orilẹede Naijiria bẹ si igboro lati fi idunnu wọn han.

Ṣugbọn bi idunnu ṣe n ṣubu layọ fun awọn

kan ni idunnu n ṣubu lu ibanujẹ fun awọn miiran. Ọpọ oun to yani lẹnu ni a ri ni igboro.

Lára awọn oun ajoji ati oun to bani lẹru ti o ṣẹlẹ nibi ajọyọ iṣẹgun Buhari naa ree:

Gọ́ta di balùwẹ̀

Image copyrightLINDAIKEJI

Ọkan lara awọn oun ti a ri ni igboro ni ọdọ kan to mu ileri rẹ ṣẹ wipe ti Buhari ba gbegba oroke, oun yoo luwẹ ninu gọ́tà.

Ni tootọ, o ṣe bẹẹ bo tilẹ jẹ pe igbesẹ naa ṣe ajoji, ti ọpọlọpọ awọn to ri aworan ọdọ naa to na ika mẹrini-mẹrin soke si n bẹnu atẹ lu u wi pe o jọ bi ẹni pe ori rẹ ko pe. Ṣugbọn bi inu awọn eniyan kan ṣe dun to ree lọna tiwọn fun esi idibo naa.

Omi ìdọ̀tí dùn lẹ́nu

Image copyrightMUH’ D KABIR WUSASA

Awọn kan tilẹ ni wiwẹ ninu gọ́ta ko to o, awọn gbọdọ mu omi ẹrọfọ lati ki ara awọn ku ori ire fun iṣẹgun Aarẹ Buhari. Okan lara awọn aworan ti a ri ni igboro fi ẹyi han nibi ti arakunrin kan ti bẹrẹ mọlẹ̀ ti o si mu omi idoti kan bi ẹni ti ina n jo ni ọ̀fun.

Ikọ̀ ọmọogun pa àwon ọ̀dọ́ mẹ́ta níbi àjọyọ̀

Image copyrightPREMIUMTIMES

Bí àwọn kan ṣe n ṣe ajọyọ̀ lọ́na to ṣe ajoji si awọn ẹlomiiran ni a gbọ pe ajọyọ awọn ọdọ kan di ibanujẹ ni ilu Yola, ni Ipinlẹ Adamawa.

Iroyin sọ wipe ní Ọjọ́ru ni awọn ọdọ kan bẹ si igboro ni Ijọba Ibilẹ Numan ni ipinlẹ naa. Ariyanjiyan ni a gbọ pe o ṣẹlẹ laarin awọn ọdọ naa ati awọn ikọ oloogun to wa nibi afara Numan.

A gbọ pe iwọde ayo naa kọkọ lọ wọrọwọ ṣugbọn wọn bẹrẹ sini fa jagidijagan ti awọn ikọ oloogun si gbiyanju lati kapa wọn.

Awọn oniroyin ni, nigba ti o di pe o nira fun awọn oloogun lati kapa awọn ọdọ naa, wọn yinbọn soke lati kilọ fun awọn ero, ṣugbọn wọn ni awọn ọdọ kan bẹrẹ si ni sọ okuta, eyi to bi awọn oloogun naa ninu, ti wọn si bẹrẹ si ni yinbọn si aarin ero naa.

Lẹyin o rẹyin, mẹta ninu awọn ọdọ naa ba iṣelẹ ọhun lọ ti ikọ oloogun si ti gbe oku wọn lọ ibi igbokusi ile iwosan Numan.

Ọ̀dọ́ kú ní Eko

Image copyrightLAGOSTELEVISION

Ayọ to di ibanujẹ yii naa de Ipinlẹ Eko nibi ta ti gbọ wipe janduku kan ti awọn eniyan ko mọ orukọ rẹ yinbọn si aarin awọn to n ṣe iwọde ayọ lori iṣegun Buhari ni agbegbe Sabo, Yaba nilu Eko.

Bi awọn ero ṣe tuka ni wọn ṣe akiyesi wipe ibọn ti ba ọdọ kan. Ni agbegbe miiran nilu Eko, awọn ọdọ to n ṣe ajọyọ iṣegun Buhari ṣe ikọlu si awọn ọlọpaa ni Alaba Rago, Okokomaiko bi wọn ṣe di oju ọna ti wọn si n ba ọja awọn oniṣowo to wa ni agbegbe naa jẹ.

Ọ̀dọ́ fi abẹ kọ́ orúkọ APC sára

A ri i bi ifẹ ẹgbẹ oṣelu APC ṣe to ni ọkan awọn ọdọ kan ni ilu Kano nibi ti akọroyin BBC ti ri ti ọkan to sọ fun ọrẹ rẹ ko ba oun fi abẹ kọ orukọ APC si ẹyin oun.

Exit mobile version