Koffi Olomide: Ilé ẹjọ́ kan nílẹ̀ Faranse ló sọ́ sẹ́wọ̀n ọdún méjì

Koffi Olomidé, ọkan nínu àwọn gbajúgbàjajà olórin takansufe nìlẹ̀ Afíríkà, ní wọn ló jẹbi ẹ̀sùn pé ó fipá bá ọ̀kan lára àwọn ọmọ tó ń ba jó lopọ, nìgbà tí ò wà ní ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dógún.

Bó tilẹ̀ jẹ pé ó kọ̀ láti yọju sí ilé ẹjọ, síbẹ, wọ́n wọn ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́jì fun ní ilé ẹjọ kan ni France.

Akoroyin BBC, Nadir Djennad jábọ̀ pé, ìtumọ̀ ìdájọ́ tí wọn dá fún gbájugbaju olorin ọmọ bibi Congo ni pe, yóò kóju àtimọ́le ní to ba tún lu òfin.

Olomidé, ẹni ọmọ ọdun méjìlélọ́gọ́ta ni wọn pàṣẹ fún pé, kó sàn ẹgbẹ̀rún márùn Euro gẹgẹ bii owó ìtanran fún oníjo rẹ̀ nígbà kan.

Bakan náà ni ilé ẹjọ Nanterre to wa ní àgbegbè Pari, tún ni ko san iye owo kan náà, nítori ó ràn àwọn obinrin méji kan lọ́wọ́ láti wọ ilẹ̀ France lanà àìtọ́

Agbéjọro Olomidé lásìkò tó ń ba àwọn akọroyin sọ̀rọ̀ sọ pé, òun ri ìgbéjọ náà gẹ́gẹ́ bi àṣeyori nítori èyí yoo yọ Koffi kúro nínú ìwé ìpẹ̀jọ àgbáyé, to fẹ fi sẹ́wọ̀n.

Koffi Olomidé jẹ ìlúmọ̀ọ́ká olórin Rumba àti Soukous, ti gbogbo ènìyàn mọ ní ọ̀pọ̀ àwọn ilẹ̀ aduláwọ̀

Sáájú ni wọn ti pe Olomidé lẹ́jọ́ lọ́dun 2012, fún ẹ̀sùn ìbálòpọ̀ sùgbọ́n nígbà tó yá ni wọn ṣe àdínkù ẹ̀sùn náà.

Mẹ́rìn nínú àwọn tro ń jó fún gbájugbajà olórin náà ló jẹ́rìí nilé ẹjọ pe ó fi ipá ba àwọn lòpọ̀ láàrín ọdun 2002 si 2006. Wọn ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáye ni DR Congo àti France.

Awọn obinrin náà tún fẹ̀sùn kàn pé ó fi àwọn pamọ sinnu ile kan ní agbegbe paris lòdi sí ìfẹ́ inu àwọn sùgbọ́n àwọn sá kúrò ni oru ọjọ́ kan lọdun 2006 ti àwọn ò si le pada si DR Congo ki ó ma ba tun mú àwọn.

Bótilẹ̀ jẹ́ pe àgbéjọro ń fẹ́ ki wọn fi si ẹ̀wọn ọdun méje síbẹ̀ adájọ dá gbogbo atotonu agbẹjọrà nù ni to fi mọ ẹsun ìjíní gbé.

Olomidé sá lọ si DR Congo lọdun 2009 pẹ̀lú ìléri pé òun yóò gbèjà ara òun sùgbọ́n ó kọ̀ láti farahan nílé ẹjọ́ ni France.

Okunrin olorin ọ̀hun tó orukọ rẹ̀ gangan ń jẹ́ Antoine Agbepa Munba tó ń ni ìsòrò pẹ̀lú òfin ní ọ̀pọ̀ ìgbà:

Ní ọdun 2018 Zambia pàṣẹ́ ki wọn fi si àtimọlé nítori pé o hùwà àitọ si ayaworan kan

Ní ọdun 2016 ọwwọ agbófinro bàá wọn si da pada sile lẹ́yìn to ṣe ọkan nínú àwọn tó ń jó fún báṣubàṣu ní Kenya.

Ni ọdún 2012 ó jẹ̀bi ẹsun ti wọn fi kan ni DR Congo nítori pe ó ṣe ẹni to ń ba gbé àwọn orin rẹ̀ síta lọ́nà ti kò tọ́, wọn si wọn ẹwọn oṣù mẹ́tà fún.

Ni ọdun 2008 wọn fi ẹsun kan pé ó gab ayàworàn kan nípàá lóri amóhùnmáworan DR Congo ti ó si fa ẹ̀rọ ayaworan rẹ̀ níbi ayẹyẹ orin itagbangba, sùgban òun àti ẹni náà fi ṣe ọ̀rọ̀ abẹ́ ilé.

Exit mobile version