2019 elections: INEC pín iwé ẹ̀rí fún àwọn aṣòfin àpapọ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dìbò yàn

Ni ọjọbọ lawọn aṣofin apapọ ti wọn dibo yan lorilẹede Naijiria gba iwe ẹri iyansipo wọn.

Ajọ INEC n fun awọn aṣoju-ṣofin atawọn sẹnetọ ti wọn yan yoo gba iwe ẹri wọn lọwọlọwọ bayii ni gbọngan nla Main Hall (Africa Hall), International Conference Centre, ni ilu Abuja.

Nibi eto naa, awọn sẹnetọ ni yoo kọkọ gba iwe ẹri ki o to kan awọn aṣoju-aṣofin ajọ.

Ajọ INEC ko tii pari gbogbo idibo si awọn ijoko ile aṣofin apapọ mejeeji yala nitori idajọ ile ẹjs lawọn agbegbe kan ati atundi idibo ti yoo waye lawọn miran.

Lara awọn ti ko ni gba iwe ẹri loni ni gomina ipinlẹ Imo, Rochas Okorocha ti ajọ INEC kede pe o bori ni ẹkun idibo Imo west ki wọn to tun yipada pe tipa-tikuuku lo fi mu oṣiṣẹ ajọ naa lati kede ara rẹ gẹgẹ bii olubori.

Lara awọn ti wọn n gba iwe ẹri loni ni Dino Melaye ti o n pada si ile naa ati gomina ipinlẹ Ogun, Ibikunle Amosun ti o n pada si ile naa ẹyin ti o ti kọkọ lọ ki o to wa jẹ gomina ipinlẹ Ogun fun ọdun mẹjọ.

Lẹyin ti awsn sẹnetọ ba gba iwe ẹri ti wọn tan ni yoo kan aṣoju-ṣofin gẹgẹ bii ajọ INEC ṣe sọ.

Exit mobile version