Ethiopia Airlines Crash: Iyanrìn làwọn ẹbí olóògbé bàálù Ethiopia rí gbà dípò òkú èèyàn wọn

Ibanujẹ nla lawọn ẹbi eeyan mẹtadinlọgọjọ, ti ọmọ Naijiria Ọjọgbọn Pius Adesanmi jẹ ọkan lara wọn, to padunu ẹmi ninu ijamba baalu Ethiopia babọ lọjọ Aiku lẹyin ti wọn fun wọn iyanri lati ibi ti baalu naa ja si dipo oku ẹbi wọn to ku.

Ko si ẹnikẹni to ri oku ẹbi wọn gba bayii lẹyin ti mwọn sọ fun wọn o kere tan o maa to oṣu mẹfa ki onikaluku to le da oku ẹbi wọn mọ.

Minisita fun eto irina lorilẹede Ethiopia Dagmawit Moges sọ pe wọn ti ayẹwo DNA fawọn ẹbi awọn oloogbe lati le ṣeranwọ nipa mimọ oku ẹnikọọkan.

Media captionCollapsed Building: Ayálégbé ló dára bí ìjọba ṣe wólé àmọ́ wọ́n fẹ́ ìrànwọ́ ilé míràn

Koda posi ti ko si oku ninu rẹ ni wọn bo mọ lẹ ni olu ilu Ethiopia tii ṣe Addis Ababa lati le maa ṣe iranti awọn to ku ninu iṣẹlẹ ọhun.

Image copyrightGETTY IMAGES
Àkọlé àwòránIjamba baalu Ethiopia

Ọgbẹni Paul Njoroge ati baba iyawo rẹ John Quindos Karanja fi ibanujẹ kuro nibi eto isinku ọhun lẹyin ti wọn ko ri oku iyawo wọn ati awọn ọmọ to ku.

Amọ ṣa, wọn iyanrin lati ibi ti baalu naa ja sinu ọra dipo oku awọn ẹbi wọn.

Image copyrightGETTY IMAGES
Àkọlé àwòránIjamba baalu Ethiopia

Bakan naa ni isin iranti isin iranti fawọn to ku waye loni niluu Nairobi nibi t’ọpọ eeyan ti ṣadura fawọn to doloogbe.

Exit mobile version