Election 2019 Updates: Atiku pe ẹjọ́ tako Buhari pẹ̀lú 20 àgbà amòfin

Oludije fun ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oselu PDP, Alhaji Atiku Abubakar ti pe aarẹ Muhammadu Buhari, to n soju ẹgbẹ oselu APC lẹjọ, wipe esi bio to gbe wọle fun saa keji lọwọ magomago ninu.

Ọjọ Aje si ni Atiku morile ile ẹjọ lati gbe atako r kalẹ, nigba to ku wakati mẹrinlelogun pere ki iye ọjọ ti ofin la kalẹ fun oludije kan lati pe ẹjọ tako esi ibo pe.

Nigba to n fi idi isẹlẹ naa mulẹ, ẹgbẹ oselu PDP ni, awọn ẹlẹri to le ni irinwo lo ti wa nilẹ bayii lati tako Buhari ati ẹgbẹ oselu APC lori esi ibo aarẹ to kọja.

Emmanuel Enoidem, tii se oludamọran nipa ofin, to bawọn akọroyin sọrọ lorukọ ẹgbẹ oselu PDP nile ẹjọ naa sọ pe, ẹgbẹ oselu naa ati oludije rẹ ninu eto idibo aarẹ to kọja, Atiku Abubakar, ti gbe iwe ẹsun wọn kalẹ ni ibujoko igbimọ olugbẹjọ ibo aarẹ, to kalẹ silu Abuja.

Enidem wa fidi rẹ mulẹ pe awọn agba amofin to to ogun niye ni yoo maa soju Atiku ati PDP ninu ẹjọ naa pẹlu afikun pe ọjọ Isẹgun oni ni ofin pa lasẹ pe ko si anfaani mọ fun oludije lati pẹjọ lẹyin ikede esi ibo.

Bakan naa ni agba amofin to wa lara ikọ agbẹjọro Atiku, eyiun amofin Mike Ozekhome naa fidi rẹ mulẹ pe ẹjọ ti Atiku ati PDP pe kii se ofuutu fẹẹtẹ, aasa ti ko ni kaun rara, nitori pe ẹjọ naa lẹsẹ nilẹ, to si tun lowura pẹlu.

Exit mobile version