Kolade Johnson: Adájọ́ pàṣẹ kí wọ́n fi ọlọ́pàá tó lọ́wọ́ nínú ikú Kolade Johnson sí àhámọ́

Inspẹkitọ ọlọpaa ti wọn yọ niṣẹ lori ọrọ arakunrin Kolade Johnson ti wọn yinbọn pa nilu Eko ti foju ba ile ẹjọ.

Adajo paṣẹ bakannaa pe ki wọn lọ fi si ahamọ titi di igba ti wọn yoo fi gbẹjọ rẹ.

Ọjọ ẹti tii ṣe ọjọ karun un ọsu Kẹrin ni ẹka ọtẹlmuye ọlọpaa to wa ni Panti nilu Eko gbe Inspẹkitọ Ogunyẹmi Olalekan lọ si iwaju adajọ.

Ninu atẹjade kan ti alukoro ile iṣẹ ọlọpaa nilu Eko,Bala Elkana fi sọwọ sawọn akọrọyin o salaye pe Adajọ ile ẹjọ kekere to wa ni Ebute Meta,Adajọ A.O Salawu paṣẹ ki wọn fi si ahamọ titi diigba ti Oludari eka olupejo labe ijoba nipinle naa yoo fi lawọn lọyẹ lori ẹjọ naa.

Ile ise ọlọpaa ti saaju gba asọ lọrun inspektọ Ogunyẹmi Olalekan lori ipa to ko ninu iyinbọn pa Kolade Johnson.

Exit mobile version