Collapsed Building: Ilé alájà mẹ́ta wó l’Eko

Awọn oṣiṣẹ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri atawọn adoola ẹmi ti ri lara awọn ọmọ ile iwe yọ nibi iṣẹlẹ ile alaja mẹta to wo ni agbegbe Ita Faji, Lagos Island ni ipinlẹ Eko.

A gbọ pe eniyan mẹsan lo ti ba iṣẹlẹ naa rin ti wọn si ti doola eniyan to to mejilelogoji.

Ìròyìn tó ń tẹ̀ wa lọ́wọ́lọ́wọ́ ní wí pé ilé alájà mẹta náà ni ilé ìwé alakọbẹrẹ kan wà nínú rẹ̀ ní agbègbè Ita faji ipinlẹ Eko.

A gbọ iroyin pe ile iwe alakọbẹrẹ yii lo wa loke patapata ile alaja ọhun. Bakan naa, iroyin sọ pe awọn akẹkọọ ti ha sabẹ ile naa.

awọn oṣiṣẹ ile iṣẹ pajawiri atawọn adoola ẹmi ti wa nibi iṣẹlẹ naa.

Bakan naa, ikọ oniroyin BBC Yoruba naa ti n ko iroyin jọ.

Exit mobile version